top of page
  • Writer's pictureBosede

ÀÌRÍ OORUN SÙN

Updated: Oct 13, 2021

KÍNI Ó Ń FA ÀÌ RÓORUN SÙN?

Àìrí oorun sùn lè ṣẹlẹ̀ tí o:

• bá mu ọtí ni wákàtí mẹrin sì àkókò oorun

• bá jẹ oúnjẹ tí ó pọ̀ju tàbí wúwo jù ni alẹ́ pátápátá

• bá mu tíì tí ó ní kòkó nínú tàbí tábà tí ó wà nínú sìgà

• bá kó ẹrú jágbajágba jọ sí orí ibùsùn rẹ tàbí kí pándukú pọ̀ ni yàrá oorun

• bá fẹ́ràn láti wo telifísàn di ọ̀gànjọ́ òru

Kini a lè ṣe?

1. Gbìyànjú láti lọ sún ni déédéé agogo kanna lójojúmọ́

2. Máse mú ọtí tàbí fí tábà tàbí jẹun ju lọ́wọ́ alẹ́

3. Sun nígbà tí oorun bá nkun ọ

4. Dìde kúrò lórí ibùsùn rẹ tí oòrùn kò bá dé lẹ́yìn ogún ìṣẹ́jú tí ó ti dùbúlẹ̀

5. Jẹ́ kí ìbùsùn rẹ ṣe wo, kí yàrá rẹ sì fà ni mọ́ra

6. Pa iná tàbí kí ó yí iná sílẹ̀ díẹ̀ láti pàrọwà fún ọpọlọ pé ilẹ̀ tí ṣú

7. Ó tún lè lo ìpara olóòrún dídùn bí láfíndá láti pèsè ara rẹ fún oorun dídùn.

8. Gbìyànjú láti ṣe ère ìdárayá tí ó ní ìjo nínú lójú ọjọ́

9. Fífi omi tí ó gbóná wọ́ọ́rọ́wọ́ wẹ̀ lè ní ànfàní pẹ̀lú

10. Tiraka láti má sún ni ọsan gangan. Tí ó bá ní láti sún oòrùn ranpe losan, ri pé kò ju wákàtí kan lọ, ó sì ní láti jẹ́, kí agogo mẹta ọsan tó lu

Láyọ̀ ó.

- Bosede Adetifa

5 views0 comments

Recent Posts

See All

Ọ̀RỌ̀ ÀPỌ́NLÉ - ADVERB

Ọ̀RỌ̀ ÀPỌ́NLÉ (Adverb) ọ̀rọ̀ àpọ́nlé ni ó ń fún wa ní ìtumọ̀ kíkún lórí ọ̀rọ̀ ìṣe nínú gbólóhùn. Fún àpẹẹrẹ : Ìyá àgbà sùn fọnfọn (sùn jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe nígbà tí fọnfọn jẹ́ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) Ǹjẹ́ ẹyin náà lè

Names by Nature

*Orúkọ àmútọ̀runwá* 1. Taiwo (Tọ́-ayé-wò) - first of twins 2. Kehinde - last born of twin 3. Ìdòwú - a child born after the twins 4. Àlàbá - a child born after Ìdòwú 5. Ìdògbé - a child born after Àlà

Orúkọ Àmùtọ̀runwá

*Orúkọ àmútọ̀runwá* 1. Taiwo (Tọ́-ayé-wò) - first of twins 2. Kehinde - last born of twin 3. Ìdòwú - a child born after the twins 4. Àlàbá - a child born after Ìdòwú 5. Ìdògbé - a child born after Àlà

Comments


bottom of page