top of page
 • Writer's pictureBosede

ÀWỌN ÀGBÀ ÀTI OÒGÙN ÀKÀPÉ


Ǹjẹ́ o ti rí ibi tí ènìyàn tí ń lo oògùn méjì tàbí jùbẹ́ẹ́ lọ lẹ́ẹ́kan ṣoṣo? Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn àgbà Yorùbá kan kò mọ oògùn tí wọ́n ń lo kó tó kú níní ìjìnlẹ̀ òye ipa ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oògùn lílò lè kó nínú ìlera ara eni.

Irú oògùn wo ni Yorùbá máa ń pe ni "Àkàpé" gan-an?

Àkàpé jẹ́ oríṣìríṣì àkópọ̀ oògùn oyínbó tí dókítà tí kọ fún ìlò ẹnikẹ́ni tí ó bá rẹ̀.

Ìwádìí fi hàn pé àwọn àgbà ní ó máa ń lo irú oògùn béè nítorí pé:

1. Dókítà lo kọọ́ fún wọn tàbí kí wọn gbà lọ́wọ́ aládùúgbò, ọ̀rẹ́ tàbí ọmọ ẹni láti ìlú míràn tàbí òkè òkun.

2. Wọn nlo ọ̀pọ̀ oògùn láti wo àìsàn tí oògùn míràn dá sílẹ̀ sí wọn lára

3. Àwọn àgbà kìí sáábà ṣe àkíyèsí ìgbàtí oògùn náà kì yóò wúlò mọ́. Tí ó bá ti ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan, wọn a fi pamọ fún ọjọ́ iwájú tàbí kí wọ́n fún àwọn ènìyàn láti gbìyànjú rẹ wò.

4. Bí wọ́n ṣe nlo tí òyìnbó náà ni wọ́n ṣe ń lo tí ìbìlẹ̀ papọ̀

5. Ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn ni wípé, bí oògùn bá ṣe pọ̀ sí, ní yóò ṣe ṣiṣẹ́ sí

6. Àwọn mìíràn kò tilẹ̀ ni sọ fún dókítà wọn pé àwọn wá lórí àwọn oògùn ìbílè tàbí èyí tí wọ́n ra lórí àtẹ

EWU TÍ Ó WÀ NÍNÚ OÒGÙN ÀKÀPÉ

1. Ìsubu

2. Ìbáṣepọ̀ oògùn tí ó lewu

3. Kí oògùn pẹ́ kí ó tó kúrò lára nítorí ọjọ́ ori

4. Ìruju tàbí kí inú ó pò pọ̀

5. Ó ṣeé ṣe kí àgbà bẹẹ di èrò ilé ìwòsàn.

6. Ó ṣeé ṣe kí ènìyàn gba ibẹ̀ kú pẹ̀lú

ÒUN TI A LE SE

1. Ẹ tẹle àwọn arúgbó yín dé ọdọ dókítà fún àlàyé ni ẹkún rẹ́rẹ́ lórí gbogbo oògùn tó wọn nlo. Kí ẹ sì jẹ olugbija wọn

2. Ẹ béèrè ohun tí kò bá yẹ yín nípa oogun naa

3. Ẹ ka ìwé ìtọ́sọ́nà yín dáadáa

4. Ẹ wà pẹ̀lú dókítà kan fún ìṣe déédéé

5. Ẹ gbìyànjú láti mú ọkàn kúrò nínú lílo ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àkàpè oogun

6. Ẹ mase ya Àmín àtìlẹ́yìn kúrò lára ìgò oògùn yín ó, kí ẹ máa bá a gbàgbé ìṣe tí ó ńṣe àti ìgbà tí a gbudọ lòó.

7. Ẹ tó àwọn oníṣègùn lọ fu ìmọ̀ràn tó péye

Láti ọwọ́ ìyá Àfin Bosede Adetifa


WHAT YOU NEED TO KNOW ABOUT POLYPHARMACY IN THE ELDERLY

(awon agba ati oogun akape)

Have you ever witnessed anyone taking two or more medication at once and on regular basis? Do you also know that some Yoruba elders do not know what medication they are taking, talkless of understanding the possible side effects?. So, what is poly-pharmacy?

Poly-pharmacy simply means the use of multiple medications for the treatment of health condition. According to a research conducted in Australia in 2019, poly-pharmacy is highly rated among older Australian citizen (www.mja.com.au)

Findings from past experience and recent phone interview with few Yoruba Elders in Nigeria and their children living overseas show that:

 • Multiple Medications are taken because they were given by doctors, neighbors, friends or sent by children living interstate or overseas

 • An attempt to treat certain condition that developed since commencement of certain drug also leads to poly-pharmacy

 • Medications are used past their use by dates because it worked well for the condition last time, so they will keep the rest for the future or share it with other family member or friends to try. (Self medicating)

 • They use herbs and prescribed medication to treat the same condition

 • Some elders believe you have to use multiple drugs for the drug to be effective (no dose, no indication and no frequency)

 • Some of them fail to inform their doctors that they are on herbs or over the counter drugs

RISK OF POLYPHARMACY IN ELDERS

 • High risk of fall with potential fracture due to interacting drug effect

 • High risk of drug to drug interaction due to multiple drug consumption

 • High risk of reduced drug clearance due to age

 • High risk of delirium or a state of confusion due to cognitive impairment associated with more than one drug use

 • High risk of hospitalization to manage side effect of drugs

 • High Potential risk of accidental death

HOW TO APPROACH THIS ISSUE

 • Attend the doctor’s clinic with the elders to assist with collaborative drug history gathering and to advocate for safety

 • Ask questions about prescribed medication and know the indication, dose and frequency of use

 • Take time to read and understand the manufacturer’s instruction or label on the packaging

 • Request a review of medications by doctor or pharmacist at regular intervals to ensure drug safety

 • Discourage the use of multiple medications where possible

 • Discourage doctor shopping – sticking with one doctor helps minimize confusion

 • Make sure all medications are well label with expiry dates and seek further advice from your health professional before taking any medications

Mrs Bosede Adetifa22 views1 comment

Recent Posts

See All

Ọ̀RỌ̀ ÀPỌ́NLÉ - ADVERB

Ọ̀RỌ̀ ÀPỌ́NLÉ (Adverb) ọ̀rọ̀ àpọ́nlé ni ó ń fún wa ní ìtumọ̀ kíkún lórí ọ̀rọ̀ ìṣe nínú gbólóhùn. Fún àpẹẹrẹ : Ìyá àgbà sùn fọnfọn (sùn jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe nígbà tí fọnfọn jẹ́ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) Ǹjẹ́ ẹyin náà lè

Names by Nature

*Orúkọ àmútọ̀runwá* 1. Taiwo (Tọ́-ayé-wò) - first of twins 2. Kehinde - last born of twin 3. Ìdòwú - a child born after the twins 4. Àlàbá - a child born after Ìdòwú 5. Ìdògbé - a child born after Àlà

Orúkọ Àmùtọ̀runwá

*Orúkọ àmútọ̀runwá* 1. Taiwo (Tọ́-ayé-wò) - first of twins 2. Kehinde - last born of twin 3. Ìdòwú - a child born after the twins 4. Àlàbá - a child born after Ìdòwú 5. Ìdògbé - a child born after Àlà

1 Comment


Felix Bankole
Felix Bankole
Dec 30, 2020

So blessed by this Mum. Eku ise ma

Like
bottom of page