top of page
  • Writer's pictureBosede

Ìtàn ìyán agba - old woman' story

Updated: Dec 16, 2021

Ní ìgbà tí mo kéré, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹ̀ tí o gba omijé ní ojú m̀i. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan ni kò yé mi ni ìgbà náà. Bẹ́ẹ̀ni kò sí ẹnì tí ó lè ṣàlàyé fún mi, bí aye ṣe rí àti bí a ṣe leè borí ìṣòro tó rọ̀mọ́ ìdàgbàsókè ọ̀dọ̀. Mo ṣá rántí pé, mo máa ń ṣú ekuru ẹnu ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni. Ǹjẹ́ kilo faa?

Bí mo bá banuje, n ó jẹgba

Bí mo bá láyọ̀, n ó jẹgba

Bí mo bá ké, n ó jẹgba

Bí mo bá dúró láàrin àgbà, n ó jẹgba

Bí mo bá joko níbi tí àgbà tí ń jíròrò, n ó jẹgba

Bí mo bá ń rìn lai mọ òpin irin àjò mi, n ó jẹgba

Bí mo bá jẹ oúnjẹ tí kò tọ́ simi, n ó jẹgba

Bí mo bá sọ̀rọ̀ lórí oúnjẹ, n ó jẹgba

Tí mo bá joko Șẹ́nu ọ̀nà jẹun, n ó jẹgba

Tí mo bá jẹun lai fọ abọ́, n ó jẹgba

Tí àwo bá ṣesi bọ́ fọ́ ni ọwọ́ mi, n ó jẹgba

Bí mo bá lọ sílè aládùúgbò mi lai gba àṣẹ, n ó jẹgba

Tí mo bá lu ọmọnìkejì mi, n ó jegba

Tí mo bá bá ọrẹ mi, Ẹ̀gbọ́n mi tàbí àbúrò mi jà, n ó jẹgba

Tí ń ò bá dìde lórí ibùsùn mi ni kété tí àkùkọ kọ ní ìdáji, n ó jẹgba

Tí ń ó bá dìde pọ̀n omi sílè ni àfẹ̀rẹ̀ mọ́jumọ́, n ó jẹgba,

Tí mo ba wo àgbà lójú nígbà tí wón mba mi ṣòrọ̀, n ó jegba

Tí mo bá gbàgbé láti wẹ̀ tàbí fọ ẹyin mi, n ó jẹgba

Tí mo bá bá àgbà jiyàn, n ó jẹgba

Tí wọn bá bá mi wí ní ilé ìwé mi nítorí ìwàa ókù káàtó, n ó délé jegba

Kòdà, ní igbati Ẹ̀gbọ́n mi kan nan mi, tí mo sì dákú, àwọn àgbà ilé Yoruba dọwọ́ àbàrà bò mí pé kí n dìde. Lọ́gan ni mo padà sáyé pelu ohun rárá.

Ó fẹrẹ̀ má sì oun ti mo lè ṣe tí kò ní mú ẹgba jíjẹ dání. Inú mi kọ́kọ́ pò pọ̀, ilé ayé fẹrẹ̀ ṣú mi tán tí mo fi ṣá tó ìyá àgbà lọ. Ìyá àgbà bá fi ìtàn balẹ̀, wọn ni: "bọ́mọde ò jìyà ẹ̀kọ́ṣẹ́, ṣé kò lè dọọ̀gá láéláé. Béèyàn ó sì kàwé kàwé, kò lè di ẹni tí ń kọ ní lọ́gbọ̀n lọla". Wọ́n ni kí n padà sí ibi tí mo ti ń bọ̀. Ìyá ó jẹ ó, ó ní o gbọ́n, tani tisa rẹ? Ìyá àgbà ní kí n foriti pé ọjọ ọ̀la yóò dára. Ọ̀rọ̀ yi ni mo dì mú títí mo fi kórè. Kódà nígbà tí ìyà àgbà kú, a ó fún mi láǹfààní láti lọ dágbére ikehin fún wọn, ó sì dùn mi. Àṣe ojú lo pẹ́ sì, ọ̀rọ̀ ìyá àgbà padà ṣẹ, iforiti lo láyé. Òní suuru nii fún wàrà kìnnìún. Ẹ ṣọra ṣe ó, ayé fẹ́lẹ́

Ó tún dọjọ́ miran ọjọ ire. Láyọ̀ o

- Iyaafin Bosede Adetifa


8 views0 comments

Recent Posts

See All

Ọ̀RỌ̀ ÀPỌ́NLÉ - ADVERB

Ọ̀RỌ̀ ÀPỌ́NLÉ (Adverb) ọ̀rọ̀ àpọ́nlé ni ó ń fún wa ní ìtumọ̀ kíkún lórí ọ̀rọ̀ ìṣe nínú gbólóhùn. Fún àpẹẹrẹ : Ìyá àgbà sùn fọnfọn (sùn jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe nígbà tí fọnfọn jẹ́ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) Ǹjẹ́ ẹyin náà lè

Names by Nature

*Orúkọ àmútọ̀runwá* 1. Taiwo (Tọ́-ayé-wò) - first of twins 2. Kehinde - last born of twin 3. Ìdòwú - a child born after the twins 4. Àlàbá - a child born after Ìdòwú 5. Ìdògbé - a child born after Àlà

Orúkọ Àmùtọ̀runwá

*Orúkọ àmútọ̀runwá* 1. Taiwo (Tọ́-ayé-wò) - first of twins 2. Kehinde - last born of twin 3. Ìdòwú - a child born after the twins 4. Àlàbá - a child born after Ìdòwú 5. Ìdògbé - a child born after Àlà

Comments


bottom of page