top of page
  • Writer's pictureBosede

Eto idena fun AKORAN -Standard precaution

Updated: Aug 1, 2022

STANDARD AND TRANSMISSION BASED INFECTION MANAGEMENT

(ṢÍṢE ÌDÈNÀ FÚN ÀÌSÀN ÀKÓRÀN TÀBÍ Ọ̀NÀ TÍ A LEÈ GBÀ DÁBÒBÒ ARA WA KÚRÒ LỌ́WỌ́ ÀJÀKÁLẸ̀ ÀRÙN BURÚKÚ)

Láti ọwọ́ Ìyáàfin Bosede Adetifa


INFECTION – ÌKỌLÙ TÀBÍ ÀKÓRÀN

TYPES OF INFECTION – ORÍṢÌÍRÍṢÌÍ ÀÌSÀN ÀKÓRÀN

Airborne transmission (àkóràn afẹ́fẹ́) e.g tuberculosis, chicken pox, measles-

Droplet transmission(àkóràn yomijáde (omi)) e.g influenza, whooping cough, rubella

Direct or indirect Contact transmission (àkóràn tààrà tàbí àkóràn àṣìṣe-tààrà) e.g viral gastroenteritis, scabies, Methicillin-resistant staphylococcus aureus (MRSA) and Clostridium Difficile


Standard precaution refers to the minimal infection prevention strategies put in place to ensure safety for all at all times. This practice is well communicated in health care settings and monitored for compliance. In the community setting this is usually not monitored as adherence depends on individual knowledge of the infection mode of transmission and understanding of the risks involved.

(Ìdiwọ̀n tàbí ìpéwọ̀n àìléwu túmọ̀ sí ohun tó kéré jù lọ fún ènìyàn láti ṣe kí á baà le dènà àjàkálẹ̀ àrùn. Ìdiwọ̀n yìí wọ́pọ̀ ní ilé ìwòsàn nítorípé wọ́n ní àwọn tí ó ńṣe alábòójútó irú ìdiwọ̀n bẹ́ẹ̀. Alábòójútó báyìí kò wọ́pọ̀ ní ìlú àfi bí oníkálukú ènìyàn bá ti gba ẹ̀kọ́ lórí ètò ìmọ́tótó tí ó leè ṣẹ́gun àrùn gbogbo).

To prevent or manage infection, you must identify potential risk and then develop strategy to minimize the risk thereby preventing major health problems.

It is important to have a mind set that all blood and body fluids are infectious with the exception of sweat. For instance, there is a high potential for you to become infected when in contact with an open wound, saliva or mucus of an infected person (Láti fa ìdíwọ́ fún àìsàn tàbí láti dáàbò bo ara ẹni lọ́wọ́ àìsàn, a ní láti ṣe àyẹ̀wò tó péye lórí ìjàm̀bá tí irú àìsàn bẹ́ẹ̀ le dá sílè, àti ohun tí a lè ṣe láti dẹ́kun rẹ̀. Ó ṣe kókó kí á níi lọ́kàn pé gbogbo omi ara yàtọ̀ sí òógùn ló ní àkóràn. Fún àpẹrẹ , ó ṣeé ṣe kí á di aláìsàn tí a bá fi ọwọ́ kan egbò , itọ́, kẹ̀lẹ̀bẹ̀ tàbí ìgbẹ́ eni tí ó ní àìsàn àkóràn tí ati dárúkọ lókè yìí).


Standard precaution: (Ìpéwọ̀n tàbí gbèǹdéke àìléwu)

Hand Hygiene - it is important to wash your hands with water and soap whenever it is soiled and immediately after using the toilet to void or open bowel. (Ẹfọwọ́ yín dáadáa pẹ̀lú omi àti ọṣẹ lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá wọ ilé ìyàgbẹ́)

Alcohol based hand Rub - If your hands are not soiled, you can use alcohol based hand rub to clean your hands and minimize bacteria or virus that resides on your hand (Lo ọtí ìrawọ́ láti dẹ́kun àjàkálẹ̀ àrùn)

Personal protective Equipment (PPE) – use gloves when handling body fluids or substances such as urine, saliva, mucus, stool or wound (lo ìbọ̀wọ́ ní ìgbà tí o bá fẹ́ gbé ìtọ̀, ìgbẹ́, itọ́ tàbí ṣe Ìtọ́jú egbò)

Mask, glasses or face shields – you can use this to protect your eyes , nose and mouth from splashes or spray of body fluids, secretion, excretions or blood (lo ìbòmú, gílàsì, ìbòjú láti dáàbò bo ojú, imú àti ẹnu rẹ kí omi ara bíi ìtọ̀, itọ́ tàbí kẹ̀lẹ̀bẹ̀ má bàa ta sí ọ lójú, ẹnu, imú tàbí ara)

Surface cleaning, disinfecting and waste disposal – Keep your kitchen bench, tables etc clean at all times, use disinfectants and dispose off any waste material and clean your bin with disinfectant to prevent infection (fọ tábìlì, ilé ìdáná àti agbègbè rẹ pàápàá jù lọ , ìkólè rẹ pẹ̀lú òógùn tí ó leè dẹ́kun àìsàn àkóràn)

Sharps disposal – ensure needles are disposed appropriately in puncture resistant containers, do not recap used needles (ríi dájú pé gbogbo abẹ́rẹ́ ni a dànù sínú agolo tí kò ṣe é bẹ́. Máṣe dábàá láti fi ìdérí abẹ́rẹ́ dé abẹ́rẹ́ tí o ti lò tán ní adé)

Linen container – dirty or soiled clothes are to be separated from clean clothes. Designated container is to be used and all family members orientated to this infection management strategy (Máṣe da aṣọ tí ó ti dọ̀tí pọ̀ mọ́ èyí tí ó mọ́. Ya apẹ̀rẹ̀ tàbí agbọ̀n kan sọ́tọ̀ fún aṣọ tí ó mọ́ àti èyí tí kò mọ́, sì jẹ́kí gbogbo ilé mọ òfin tí wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé).

Contact your clinic or doctor immediately if you suspect serious illness that may be due to droplet transmission, as you may need private room for your treatment thereby protecting family members and the community at large (Yára késí wọn ní àgọ́-ìwòsàn rẹ tàbí kí o pe dókítà rẹ fún àyẹ̀wò tó péye ní gbàrà tí o bá funra pé àìsàn àjàkálẹ̀ àrùn ńṣe ọ́. Ó ṣeé ṣe kí o nílò yàrá ọ̀tọ̀ fún Ìtọ́jú tí ó péye. Nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò dáàbò bo ìdílé è rẹ àti ìlú lápapò


Ref: WWW2.HEALTH.VIC.GOV.AU today 29/11/2020

8 views0 comments

Recent Posts

See All

Ọ̀RỌ̀ ÀPỌ́NLÉ - ADVERB

Ọ̀RỌ̀ ÀPỌ́NLÉ (Adverb) ọ̀rọ̀ àpọ́nlé ni ó ń fún wa ní ìtumọ̀ kíkún lórí ọ̀rọ̀ ìṣe nínú gbólóhùn. Fún àpẹẹrẹ : Ìyá àgbà sùn fọnfọn (sùn jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe nígbà tí fọnfọn jẹ́ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) Ǹjẹ́ ẹyin náà lè

Names by Nature

*Orúkọ àmútọ̀runwá* 1. Taiwo (Tọ́-ayé-wò) - first of twins 2. Kehinde - last born of twin 3. Ìdòwú - a child born after the twins 4. Àlàbá - a child born after Ìdòwú 5. Ìdògbé - a child born after Àlà

Orúkọ Àmùtọ̀runwá

*Orúkọ àmútọ̀runwá* 1. Taiwo (Tọ́-ayé-wò) - first of twins 2. Kehinde - last born of twin 3. Ìdòwú - a child born after the twins 4. Àlàbá - a child born after Ìdòwú 5. Ìdògbé - a child born after Àlà

Comments


bottom of page