top of page
  • Writer's pictureBosede

Orúkọ rere

Bí orúkọ ènìyàn bá bàjẹ́, ayé onítọ̀hún ló bàjé, Àbí ẹ̀yin rí ẹni tó bí ọmọ rẹ̀ tán, tó sọọ́ ní Júdásì.. Ká pàjùbà silẹ̀ dé iṣu alọ̀lọ̀, ká j’órúkọ rere, tó dùn sílẹ̀, d'ọmọ ẹni. Màlúù kú tán, ó fi ìṣẹ́ sílẹ̀ f’áwọ. Iṣẹ́ réré Ènìyàn lo n f’ọhùn l’ẹ́yìn ènìyàn. Orúkọ réré ló yẹ kí ènìyàn o máa jẹ. Orúkọ rere sàn ju owó lọ. Bi aráyé bá n dá orúkọ ènìyàn mọ́ ohun búburú, ó yẹ kí ẹni náà ó ronú ara rẹ̀ wò, kó ronúpìwàdà. Ẹni tó jalè lẹ́ẹ̀kan, tó bá dáràn borí, aṣọ olè ló dà bora. Ìbàjẹ́ ọjọ́ kan kò tán lógún ọdún. Ẹsin dára l’ágódóngbó. Màlúù dára l’ẹ́gbọrọ. Ìyàwó dùn l’ọ́sìngín. Ajá òyìnbó dára, Sugbon o kú àti ṣ’ọdẹ. Ènìyàn dára tán, kò n’íwà. Ènìyàn kìí rajo, kó gbàgbé ìwà rẹ sile. Ìgbín kìí tóbi kọjá ikarahun rẹ, enìyàn kìí dára jù ìwà rẹ lọ, torípé ìwà eniyan ló lè fún-un ní orúkọ rere.

Orúkọ rẹ kò níí bajẹ. O kò níí b'áwọn j’órúkọ l’ọ́gbà ẹ̀wọn, lasẹ Èdùmàrè.

Èdè Yorùbá kò níí parun. ÀṢẸ

12 views1 comment

Recent Posts

See All

Ọ̀RỌ̀ ÀPỌ́NLÉ - ADVERB

Ọ̀RỌ̀ ÀPỌ́NLÉ (Adverb) ọ̀rọ̀ àpọ́nlé ni ó ń fún wa ní ìtumọ̀ kíkún lórí ọ̀rọ̀ ìṣe nínú gbólóhùn. Fún àpẹẹrẹ : Ìyá àgbà sùn fọnfọn (sùn jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe nígbà tí fọnfọn jẹ́ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé) Ǹjẹ́ ẹyin náà lè

Names by Nature

*Orúkọ àmútọ̀runwá* 1. Taiwo (Tọ́-ayé-wò) - first of twins 2. Kehinde - last born of twin 3. Ìdòwú - a child born after the twins 4. Àlàbá - a child born after Ìdòwú 5. Ìdògbé - a child born after Àlà

Orúkọ Àmùtọ̀runwá

*Orúkọ àmútọ̀runwá* 1. Taiwo (Tọ́-ayé-wò) - first of twins 2. Kehinde - last born of twin 3. Ìdòwú - a child born after the twins 4. Àlàbá - a child born after Ìdòwú 5. Ìdògbé - a child born after Àlà

1 commentaire


Yhemmie Pompey
Yhemmie Pompey
06 mai 2022

Ododo oro

J'aime
bottom of page